Our Services



News From The BBC

A Yoruba Perspective


Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ìjọba ìpínlẹ̀ Eko dá àwọn olùgbé ìlú Eko kan padà sí ìpínlẹ̀ wọn l'Osun?
Iroyin naa to lu ori ayelujara pa sọ pe ni ṣe lawọn ọlọpaa sa awọn ọdọ kaakiri lawọn oju popo kan niluu Eko ti wọn si fi ọkọ akero nla ko wọn pada si ipinlẹ Osun.

Àgbàrá òjò gbé ọgọ́fà èèyàn lọ
Ajọ to n ri si ọrọ oju ọjọ ni Brazil jẹ ko di mimọ pe ko si nnkan meji to fa agbara yii to kọja ojo arọọrọda to rọ lọ.

Ìjọba fáwọn olùgbé ilé àkọ́patì Ikoyi Tower l'Eko lọ́jọ́ méjì láti kúrò níbẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ̀ọ́...
Kọmiṣọna fọrọ eto ayika ati ọrọ omi nipinlẹ naa, Tokunbọ Wahab lo sọ eyi di mimọ lasiko to ṣe abẹwo si agbegbe naa, nibi ti awọn eeyan n sun si lai gba aṣẹ.

Wo bí àṣírí ọ̀gá bánkì tó rí ẹ̀wọn ọdún mọ́kànlélọ́gọ́fà he lórí ẹ̀sùn jìbìtì N112m ṣe tú
Adajọ S. N. Odili gbe idajọ naa kalẹ lẹyin to ni awọn ẹri toun ri gba lori ẹsun ti wọn fi kan Placidus kọja ohun ti wọn le dawọ bo mọlẹ.

Akẹ́kọ̀ọ́ Kwara méjì fakọyọ nínú ìdánwò JAMB, gba máàkì 358 àti 362
Akekọọ ile ẹkọ girama ipinlẹ Kwara wa lara awọn akẹkọọ to fakọyọ julọ ninu idanwo JAMB ọdun 2024.

Àwọn ọ̀dọ́ bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn l’Osun lórí ọ̀wọ́ngógó epo, iná mọ̀nàmọ́ná àti oúnjẹ
Iwọde naa lo waye niluu Osogbo nipinlẹ Osun.

Ẹnikẹ́ni tó bá ṣe owó náírà ní ìṣekúṣe lọ́wọ́ yìí yóò fojú winá òfin – Mínísítà ètò ìròyìn
Minisita eto iroyin sọ pe naira jẹ iṣura ''orilẹede wa, nitori naa, ko si ẹni to maa ri bi wọn ṣe n tẹ iṣura mọlẹ ti inu rẹ maa dun.’’

Adájọ́ àgbà ìpínlẹ̀ Ogun dá ẹlẹ́wọ̀n mẹ́ta sílẹ̀, ó ní kí wọ́n má d'ẹ́ṣẹ̀ mọ́
Onidajọ Mosunmọla Dipẹolu paṣẹ yii lasiko abẹwo rẹ si ọgba ẹwọn to wa niluu Ilaro, ijọba ibilẹ Guusu Yewa.

Afurasí ìbejì tó n jalè dèrò àtìmọ́lé l’Ekiti
Ninu atẹjade ti ọga ọlọpaa Ekiti, Adeniran Akinwale gbe jade, eyi ti Sunday Abutu to jẹ agbẹnusọ buwọ lu laipẹ yii lo ti jẹ ko di mimọ pe ilu Ado-Ekiti lọwọ ti tẹ awọn mẹrẹẹrin.

Àjọ EFCC mú ẹ̀rí tuntun lọ sílẹ̀ ẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ Emefiele
Rotimi Oyedepo to jẹ agbẹjọro EFCC ni awọn ẹri naa ni awọn gba lati ọdọ amugbalẹgbẹ Godwin Emefiele tẹlẹ, ṣaaju asiko ti yoo yọju siwaju ile-ẹjọ lati sọ tẹnu rẹ.

Ìjọba Nàíjíríà sọ̀rọ̀ lórí ikú Daniel Anjọrin ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tí wọ́n gún pa ní London
Yatọ si eyi, Hainault tun wa lara awọn agbegbe ti awọn eeyan n wa julọ lori ikanni ayelujara ti Google lasiko yii.

Ìjà parí! Ogogo àti Yinka Quadri dìmọ́ ara wọn lẹ́yìn tí Ajobiewe báwọn dá si
Ṣáájú ni àwọn ìròyìn kan ti ń lọ lórí ayélujára pé nǹkan kò lọ déédé láàárín àwọn àgbà òṣèré méjéèjì láti ọdún tó kọjá àmọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò gbàgbọ́.

Ìjì líle gba ẹ̀mí èèyàn mẹ́wàá, àwọn 20 di àwátì
Afẹfẹ iji lile naa lo fa agbara ojo nla, eyi to ṣakoba fun iku awọn eeyan naa, ati bi awọn ogun tun ṣe poora.

Kí ló fa aáwọ̀ tó jẹ́ káwọn afurasí jàndùkú dáná sun ọjà Ile-Epo l'Eko?
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti kede pe awọn ti fọwọ ṣinkun ofin mu aadọta afurasi janduku ti wọn dana sun ọja Ile-Epo lagbegbe Abule Egba nipinlẹ Eko ni Ọjọbọ ọjọ keji oṣu Karun ọdun 2024 yii.

Ọmọọba Harry àti Meghan Markle fẹ́ ṣàbẹ̀wò sí Naijiria l’oṣu karun-un
Invictus Games ni idije ere idaraya ti wọn ṣagbekalẹ rẹ fawọn oṣiṣẹ ologun ati agbofinro ti wọn farapa loju ogun, lati maa fi dun wọn ninu.

Israel/Gaza: Ẹ jọ̀wọ́ ogun sílẹ̀ kí ọmọ mi le wálé
Iya Hersh ni ibanujẹ lo jẹ nigba ti oun ri fọnran naa.

A ti mú Ibrahim Abdullahi tó wà nídi ìkọlù sí èrò inú reluwé Kaduna sí Abuja- Ọlọ́pàá
Olumuyiwa Adejọbi sọ pe Ibrahim Abdullahi lorukọ ọkunrin naa, ati pe Mande ni inagijẹ ti ọpọ awọn eeyan mọ ọn si.

A ti mọ ọlọ́pàá tó yìnbọn pa Toheeb Eniafe ní ilé-epo ní Eko- Ọlọ́pàá
Ṣugbọn sibẹ, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ti fidi rẹ mulẹ pe ọlọpaa ni ẹni naa, ati pe Special Protection Unit (SPU) Base 17 to wa ni Lion Building l’Eko lo ti n ṣiṣẹ.

Àwọn ẹ̀ṣọ́ aṣọ́bodè pápákọ̀ òfurufú Heathrow ní London daṣẹ́ sílẹ̀ ṣùgbọ́n....
Awọn oṣiṣẹ naa pinnu lati bẹrẹ iyanṣẹlodi yii lati fẹhonu han lori iyipada to fẹ ba bi wọn ṣe n ṣiṣẹ.

Agbẹjọ́rò wọ́ Adelabu àtàwọn míì lọ sílé ẹjọ́ fẹ́sùn pínpín iná mọ̀nàmọ́ná sí ìsọ́rí
Àwọn mìíràn tí Akingbolu tún pé lẹ́jọ́ ni àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ iná mọ̀nàmọ́ná Nàìjíríà, Nigeria Electricity Regulatory Commission (NERC) àti Ikeja Electricity Distribution Company (IKEDC).

Ojú mi ri tó lẹ́yìn tí ìyàwó mi jáde láyé ní ọjọ́ kẹta tó bí ìbẹta- Gafar
Gafar ní ìdùnnú àwọn tún lékún nígbà tí àwọn lọ ṣe àyẹ̀wò, tí wọ́n sì sọ fún àwọn pé ìbejì ló wà nínú ìyàwó òun.

Wọ́n fẹ̀sùn kan Israel pé wọ́n ń pète ogun nípa ìṣekúpa ọmọdé
Ninu iwadi sini ikọ ologun Israel ni West Bank, BBC ṣe afihan ohun to waye lọjọ ti awọn ọmọdekunrin meji naa ku.

Ìjọba Nàíjíríà sọ̀rọ̀ lórí ikú Daniel Anjọrin ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tí wọ́n gún pa ní London
Yatọ si eyi, Hainault tun wa lara awọn agbegbe ti awọn eeyan n wa julọ lori ikanni ayelujara ti Google lasiko yii.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko tún ṣàwárí abẹ́ afárá ni Osborne ní Island tí àwọn èèyàn n gbé
Tokunbọ Wahab ni abẹ afara Osborne to wa ni Ikoyi lawọn ti ṣawari ibi ti awọn eeyan naa sọ di ile wọn lati maa gbe.

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fún ìjọba di ìparí oṣù yìí láti san N615,000 owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ tí wọ́n ń bèèrè
Gomina ipinle Eko, Babajide Sanwo-Olu ti sọ pe ijọba oun ṣetan lati san owo oṣiṣẹ to kere julọ ti ijọba apapọ ba kede.

Kò sí nǹkan tó máa dá ìkọlù wa sí Rafah dúró - Netanyahu
Eyi lo jade lasiko ti igbinyanju pe ki adehun waye pe ki awọn juwọ ogun silẹ, ti wọn si tu awọn eeyan to wa ni ahamọ silẹ.

Àwọn afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn pa èèyàn kan, jó ilé ìgbé méjì gbúrúgbúrú ní Kwara
Iroyin ni lalẹ ọjọ Aje, ọjọ Kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 ni rogbodiyan bẹ silẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ti wọn si faa titi di ọjọ Iṣẹgun.

“Lẹ́yìn ọdún kan tí wọ́n fi ipá bá ọmọ mi ọmọ odún mẹ́ta lòpọ̀, mò ń wá ìdájọ́ òdodo”
“Nnkan to ṣẹlẹ si ọmọ mi, mi o fẹ ko ṣẹlẹ si ọmọ ẹlomiran.”

Òjò ńlá àti omíyalé ṣekúpa èèyàn tó lé ní 40
Ojo arọrọda to lagbara lo fa iṣẹlẹ naa, ti o si tun sọ ọpọlọpọ eeyan di alai ni ile lori lẹyin ti Damu to wa ni Kamuchiri ni iwọ oorun Kenya ya.

Ọjọ́ àwọn òṣìṣẹ́ lágbàáyé: Ìdí tí wọ́n fi yan ọjọ́ àkọ́kọ́ oṣù Karùn-ún?
Lẹyin ti Ogun Agbaye akọkọ pari, ti ayipada rere ti n ba awọn oṣiṣẹ, ti idagbasoke ti n de pẹlu iyanju awọn ajafẹtọọ ọmọniyan ni Russia, o dohun ti awọn oṣiṣẹ n beere ohun gbogbo to tọ si wọn kaakiri aye.

Sola Sobowale ṣàlàyé bí ó ṣe rìn ìrìnàjo láti ayé 'Toyin Tomato' lọ ṣé 'Caregiver' ni London
Ilumọka oṣere, ẹni ọdun mejidinlọgọta tan imọlẹ si awọn iṣẹlẹ yii lasiko to n ṣe ifọrọwerọ lori eto Teju Baby Face lọjọ Isẹgun.

Iléeṣẹ́ O Pay ti dá a padà fún CBN, wọ́n si bá àwon Oníbàárà wọn sọ̀rọ̀ pé...
Àwọn ilé iṣẹ́ bíi Opay, Kuda Bank, Palmpay àti Moniepoint ni ọ̀rọ̀ náà kàn, tí wọn kò ní ní àǹfàní láti gba àwọn oníbàárà tuntun láàyè láti ṣí akoto owó pẹ̀lú wọn fún ìgbà kan ná.

A ó fòfin dé 'Loan App' tó bá ń dún kookò mọ́ àwọn onîbàárà wọn- FCCPC
Ọga fun ileeṣẹ ijọba, Federal Competitiona & Consumer Protection Commission, FCCPC ni idunkoko yoo di ohun igbagbe laipẹ.

Kí ló fa gbas-gbos láàrin Davido àti Wizkid lórí ayélujára?
Ori itakun ayelujara X ni rogbodiyan naa ti waye lopin ọsẹ.

Wo ohun tí àwọn aráàlú ń là kọjá nítorí àìrí epo bẹntiróòlù rà lónìí
Bo tilẹ jẹ pe ajọ NNPCL to n ri si ọrọ epo rọbi sọ lopin ọsẹ wi pe awọn ni epo to to ọmọ Naijiria lo ni ipamọ, alukoro ẹgbẹ IPMAN, Ọgbẹni Chinedu Ukadike ti fidi rẹ mulẹ pe ko si epo to to araalu lo ni Naijiria lọwọ yii.

Wo àwọn nǹkan méje tí o kò mọ̀ nípa Egbin Orun, akọrin ẹ̀mí tó dolóògbé
Olorin ẹmi bii tiẹ, Esther Igbẹkẹle, lo fi iroyin iku naa soju opo Instagram rẹ lọjọ Satide, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹrin yii.

'Ìbejì ni wá ṣùgbọ́n àyẹ̀wò DNA ní bàbá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló bí wa'
Awọn onimọ sayensi ṣalaye pe, iru iṣẹlẹ yii ṣọwọn, ti ko si ju mẹwa lọ to ni akọsilẹ lagbaye ṣugbọn o wọpọ laarin ẹranko.

Oyún oṣù méje ààbọ̀, tí Dókítà gbé jáde nínú ìyá rẹ̀ ní Gaza, ti jáde láyé
Ẹlẹmi gba ẹmi ọmọ jojolo naa ni Ọjọbọ ana, ti wọn si ti sin i si ẹgbẹ iya rẹ ẹni ti wọn fi orukọ rẹ sọ ọ.

Ìwọ́de gbòde ní Australia láti fòpin sí pípa àwọn obìnrin lọ́nà àìtọ́
Olóòtú ìjọba Australia, Anthony Albanese ní ọ̀rọ̀ náà ti di ohun tó ń dààmú gbogbo orílẹ̀ èdè àwọn.

Kí ló dé tí àwọn èèyàn kan ń fi apá jánú lórí ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀yọ́?
Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) n'ipinlẹ Ọyọ ti fi ọrọ lede wi pe irọ lasan ni pe eto idibo naa lọ ni irọwọrọsẹ,

Mọ̀ nípa ẹgbẹ́ kan tó wà fún àwọn obìnrin tí kò fẹ́ l'ọ́mọ láyé
Ileeṣẹ BBC ba awọn obinrin to jẹ ọmọ ẹgbẹ Bristol Childfree Women sọrọ, wọn si salaye idi ti wọn ri ti wọn fi pinnu igbesẹ yii.

Wo pàtàkì iṣan tó ń ṣiṣẹ́ bíi ọkàn, mú kí èèyàn fẹsẹ̀ méjì rìn, ó tún ń mú kí ẹ̀jẹ̀ ṣàn lára
Dokita Carles Pedret, akọṣẹmọṣẹ lati ileewe to n ri si ilera nipa ere idaraya ni Yunifasiti Barcelona ni iṣan Soleus nilo lati maa ṣiṣẹ deede keeyan le wa lalaafia ara.

Local Housing

This is one of the main issues facing local people. The inadequacy of social housing stock continues to be the main concerns of local people. And it is getting worst.

Read More

Drugs And Illegal Substances

Taking illegal drug is always fraught with danger. You don't need me to tell you that - your grand mother will say the same. The high very often tend to perpetual low that you will never get out from. Get advise now before it is too late

Read More

Knife Attacks

Who goes around with a knive as weapon of protection is deluded. It will inevitably be your comeuppance. Just in case you do not understand, it will kill you. There is no justification for carrying a knive excerpt when you are foraging in the jungle.

Read More

Gang Culture

We were all young once - doing things adults will frown upon. This was at school or in the play grounds. But as we grew up, people we wanted to associate with start to shrink in numbers as our brain matured correspondingly and as a result doing the right thing. Pick your friends judiciously.

Read More

Local Parks

From a personal experience - the local park is a refuge for meditation,physical exploration and mental rejuvination. Just go for a slow run and see how you feel afterwards. Physical and mentally rewarding. Don't just take my words for it - it is a scientific fact. Please do try it.

Read More

24/7 Support

We are your one stop local solution advocate. Dont't carry all that weight on your own we are here to not only relief some of it, but to help you get back to you again.

Read More
Established since 2000

We Are Ready To Assist